Take a fresh look at your lifestyle.

Àwọn Olùfi Ẹ̀hónú Hàn padà sí Ojú pópó ní Orílẹ̀ Èdè Sudan

0 255

Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Sudan ti ya sí ojú pópó ní olú ìlú orílẹ̀ èdè náà, Khartoum láti pèpè fún pípadà sí ètò ìjọba tiwa-n-tiwa, lẹ́yìn tí àwọn ológun ti dìtẹ̀ gba ìjọba ní ọdún tí ó kọjá.

 

ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn jáde pẹ̀lú àkọlé àti fọ́to àwọn tí ó ti fi ẹ̀mí wọn jìn fún ìdápadà ìjọba àwa arawa.

 

Wàhálà ìwọ́de náà bẹ̀rẹ̀  láti inú osù kẹẹ̀wá tí ó kọjá nígbà tí ọ̀gágun Abdel Fattah al Burha fi ipá gba ìjọba.

Leave A Reply

Your email address will not be published.