Take a fresh look at your lifestyle.

Ìbásepọ̀ Orílẹ̀ Èdè Nàìjíríà Pẹ̀lú United Kingdom Múnádóko

0 69

Asojú àgbà orílẹ̀ èdè United Kingdom Catriona Liana, sí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà  sọ pé ìbásepọ̀ láàrin orílẹ̀ èdè méjéèjì nípa ètò ààbò, ọrọ̀ ajé, ohun àmúsagbára gún régé, àtipé orílè èdè United Kingdom kò fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú àjọse náà.

 

Ó fi ọ̀rọ̀ náà léde nígbà tí ó ń se ìrántí ìgbé ayé rere tí ọbabìnrin Elizabeth  gbé, ní nìlú Àbújá. Ó tún sàlàyé pé ìbásepọ̀ ọlọ́jọ́ pípẹ́ ni ó wà láàrin orílẹ̀ èdè méjéèjì náà.

 

Liang se àfikún pé Ọba tìtun Charles náà yóò fi ẹsẹ̀ lé ọ̀nà àlàáfíà tí obabìnrin náà tọ̀ nígbà ayé rẹ̀ àtipé yóò mójú tó ọ̀rọ̀ àyípadà ojú ọjọ́. Ó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, wọn yóò bo òkú ọbabìnrin Elizabeth mọ́lẹ̀ ní ọjọ́ kọkàndílógún, osù kẹẹ̀sán, ọdún 2022.

Leave A Reply

Your email address will not be published.