Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko labẹ Oludari Ile Aṣofin naa, Aṣofin Mudashiru Ọbasa ti fọwọ si ofin ti o nii ṣe pẹlu ọna iwadii pataki ti o nii ṣe pẹlu ẹya ara ati Ile-iṣẹ fun iwadii pẹlu imọ sayẹnsi. Abadofin naa ti wọn pe ni ‘A Law Establishing Lagos State Deoxyribo-Nucleic Acid (DNA) and Forensic Centre’ ni wọn sọ di ofin ninu ijiroro ile lọjọ Aje, ‘Monday’ to kọja, lati fi ṣeranlọwọ fun eto igbẹjọ ododo ati ni irọrun ni Ipinlẹ Eko.
Lara erongba ofin tuntun yii ni lati maa ṣamulo ilana igbalode DNA lati fẹri ododo ọrọ kan mulẹ. Bakan naa ni ile-iṣẹ tuntun imọ ijinlẹ ‘Forensic’ yii yoo maa ṣayẹwo ẹya ara bi ika, omi ara, oogun, ohun ija-ogun, ohun elo iṣẹ ati awọn nnkan miiran to ṣe pataki lọna igbalode lati fi ododo ẹri kan mulẹ.
Bakan naa ni yoo maa pese awọn abajade ilana eya ara DNA fun iwadii ẹsun ọdaran lati fi otitọ ọrọ mulẹ laini fi iya jẹ alaimọ. Yoo ṣe agbekale aka iroyin (Data base), ilana to yẹ ati Ibi ti wọn yoo maa ko awọn nnkan ẹya ara ti wọn gba lara ẹnikan fun iwadii si. Bakan naa ni ofin yii fun ile-iṣẹ yii lagbara lati mọ iṣori awọn eniyan ti wọn yoo maa ṣe iwadii DNA yii fun ati kiko awọn ẹri jọ ti wọn yoo le lo, fun iwadii ẹsun iwa ọdaran kan.
Ofin yii tun fun ile-iṣẹ yii lagbara lati mọ ibaṣepọ enikan ninu ẹbi kan, ti wọn yoo fi mọ ọmọ ẹni ti ẹnikan n ṣe, ti ko fi ni si ariyanjiyan kan.
Ẹwẹ, ile-iṣẹ yii ni ireti wa pe yoo ṣagbekalẹ awọn ọna ti wọn yoo fi ṣamulo awọn ilana ati imọ-ẹrọ to jẹ mọ lilo ọna igbalode DNA yii.
Leave a Reply