Gómìná Muhammadu Inuwa Yahaya ti Ìpínlẹ̀ Gombe sọ pé ìjọba ìpínlẹ̀ gombe ń wá láti pèsè àwọn ilé gbígbé ẹgbẹ̀rún tí owó rẹ̀ kò ní ga jara lọ àti wípé yóò ṣe gbà fún àwọn tí ò ní owó púpọ̀ tàbí àwọn tí owó oṣù wọn kò gbé pẹ́lí.

Gómìná tó sọ èyí di mímọ̀ lásìkò ìpàdé pẹ̀lú adarí àgbà àti ọ̀gá àgbà fún ètò ìnáwó ilé ẹbí, Ọ̀gbẹ́ni Femi Adewole, nílùú Abuja, so pé lábẹ́ ètò ìnáwó ilé ọ̀ wún, iṣé àkànse náà yóò ní yàrá kíní, kejì, àti kẹta nínú ilé náà.
Ọláyinká Akíntọ́lá.
Leave a Reply