Inú dídùn ló ń móríwú: Àjọ tó mójútó ètò eré ìdárayá lórílẹ̀dè Nàìjíríà ti fún àwọn tó gba àmì ẹ̀yẹ nínú ìdíje àjọ comonwealth ní nkàn ìmóríwú
Àjọ tó mójútó àwọn ọ̀dọ́ àti Ìdàgbàsóké Eré-ìdárayá ná owó tó tó $25,000 fún àwọn eléré ìdárayá órílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó ti gba àmì-ẹ̀yẹ nínú ìdíje eré Birmingham àjọ Commonwealth, ọdún 2022 tí ńlọ lọ́wọ́ ní United Kingdom.
Nínú ayẹyẹ náà tó wáyé ní Ọgbà Hilton ní Birmingham, àwọn eléré ìdárayá àti àwọn olùkọ́ni wọn gba èrè fún bí wọ́n ṣe mú ògo bá órílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Àwọn tó gba àmì-ẹ̀yẹ góòlù, Adijat Adenike Olarinoye àti Rafiatu Folashade Lawal, gba $5,000 lọ́kànkan, nígbà tí àwọn olùkọ́ni wọn gba $3,000 lọ́kànkan, Taiwo Laidi, tó gba àmì-ẹ̀yẹ fàdákà nínú eré irin gbígbé oní 76kg àwọn obìnrin, gba $3,000 fún ìgbìyànjú rẹ̀.
Fún àwọn tí ó gba àmì-ẹ̀yẹ idẹ, Edidiong Joseph Umaofia, Islamiyat Yusuf àti Mary Osijo, gbogbo wọn náà gba $2,000 lọ́kànkan fún ìgbìyànjú wọn.
Folashade gba àmì-ẹ̀yẹ góòlù nínú ìdíje irin gbígbé oní 59kg ti àwọn obìnrin, nígbà tí Adenike náà gba àmì-ẹ̀yẹ góòlù nínú ìdíje irin gbígbé oní 55kg ti àwọn obìnrin.
Ọláyinká Akíntọ́lá.
Leave a Reply