ÌPÍNLẸ̀ ẸNÚGU: Ilé Iṣẹ́ Àwọn Ọmọ Ogun Nàìjíríà Bu Ọlá Fún Àwọn Ọmọ Ogun Fún Iṣẹ́ Takuntakun Wọn
Ilé Iṣẹ́ àwọn ọmọ ogun Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti bu ọlá fún áwọn ọmọ ogun mẹ́rin fún iwa aìsè ìmẹ́lẹ́ ati isẹ́ takuntakun wọn lẹ́nu isẹ́.
Orúkọ àwọn Sójà náà nìyí :Sójà Olókùn mẹ́rin, Amodu Simon, Olókùn mẹ́ta, Oyinbo Emmanuel, Olókùn méjì, Corporal Mbanaso Isaac àti Private Ibrahim Lawal, ni wọ́n dá lọ́lá ní Abakpa Cantonment ní ìpínlẹ̀ Ẹnugu.
Olúkúlùkù wọn ni wọ́n tẹ́wọ́ gba lẹ́tà ìgbóríyìn ati kẹ̀kẹ́ Alùpùpù tuntun kọ̀ọ̀kan láti ọ̀dọ̀ Alakoso Gbogbogbo wọn (GOC) 82 Division, Major General Taoreed Lágbájá.
Major General Lágbájá ṣàpèjúwe ìwà àti àpẹẹrẹ rere àwọn Sójà náà gẹ́gẹ́bí èyítí ó yẹ láti gbóríyìn fún, tó sì wúni lóri, ó gba àwọn akẹgbẹ́ wọn yóku ní ìmọ̀ràn láti ṣe àfarawé ìwà rere wọn tó yàtọ̀.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
Leave a Reply