Olùrànlọ́wọ́ Akọ̀wé fún Ìṣúra ni Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, Jonathan Burke yóò ṣè àbẹ̀wò sí Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti ọjọ́ kẹtàlélógún sí ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kejì, láti mú kí àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Ìjọba Nàìjíríà lágbára síi lórí gbígbógun ti owó ìnáwó àwọn apanilaya.
Nínú ìròyìn kan láti ọwọ́ Ilé Iṣẹ́ Ààbò ni Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ní Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ìbẹ̀wò náà jẹ́ ara àwọn ìsapá Ìjọ́ba Trump láti dín ìwà ipá sí àwọn Kristẹni àti àwọn ẹgbẹ́ mìíràn tí ó ní ìṣòro kù.
Nígbà tí ó wà ní Nàìjíríà, a retí wí pé Burke yóò pàdé pẹ̀lú Àwọn Aláṣẹ Ìjọba àti Àwọn Olùníláárí Ẹ̀ka Àdáni láti jíròrò bí a ṣe lè kojú àwọn ewu sí ẹ̀ka ìnáwó àti àwọn ìgbésẹ̀ láti mú kí ẹ̀ka náà lágbára síi àti láti dáàbòbò.