Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ṣe Ìtẹ́tisí Aráàlú Lórí Àbá Dófin Ìnáwó Ọdún 2026

53

Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Nàìjíríà ní ọjọ́ Ajé ṣe ìtẹ́tísí àwọn aráàlú lórí àbá dòfin ìnáwó ọdún 2026 ti Ọgọ́ta dín díẹ̀ tirílíọ̀nù Náírà (N58.47 trillion).

‎Ìpàdé náà, tó jẹ́ ara ìlànà àtúnyẹ̀wò lórí ìwé ẹsuna tí Ààrẹ Bola Tinubu fi ṣọwọ́ sí ilé-ìgbìmọ̀ aṣòfin àpapọ̀ ní ọjọ́ kọkàndínlógún oṣù Kejìlá, ọdún 2025, pẹ̀lú èrò láti gbá ìmọ̀ràn àwọn aráàlú, títí dé ori àwọn àjọ ‘Civil Society Organizations’ (CSOs), àwọn olórí ilé iṣẹ́, àti àwọn alábáṣiṣẹpọ̀ ìdàgbàsókè.

‎Ọ̀jọ̀gbọ́n Wasiu Adeoye ti Yunifásítì ti Èkó gbé ìṣàyẹ̀wò ìwé ìlànà ìnáwó náà kalẹ̀ nígbà tó ń ṣàlàyé ìwé náà.

‎Àwọn ìgbìmọ̀ ìṣàkóso ọrọ̀-ajé tí Orílẹ̀-èdè, tí Mínísítà ètò ìnáwó jẹ́ Olórí fún náà ṣe àgbékalẹ̀ ìwòye tí wọ́n nínú ìpàdé náà.

‎Àwọn ilé iṣẹ́ ìjọba, àwọn ẹ̀ka, àti àwọn ilé iṣẹ́ kékèké mìíràn tí ìjọba àpapọ̀ (MDAs) yóò máa ṣàlàyé ìnáwó tí wọ́n titi di ọjọ́ kẹtàlá oṣù kejì, ọdún 2026.

‎Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ń ṣiṣẹ́ láti rí i dájú pé a ṣe àyẹ̀wò ìnáwó náà dáadáa, pẹ̀lú àwọn ìròyìn láti ọ̀dọ̀ àwọn ìgbìmọ̀ àwọn aṣòfin tí a gbọ́dọ̀ parí láàárín ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kejì sí ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù kejì, ọdún 2026.

Comments are closed.

button