Ààrẹ Bola Tinubu yóò ṣe ìbẹ̀wò sí Orílẹ̀-èdè United Kingdom láti ọjọ́ kejìdínlógún sí ọjọ́ kọkàndínlógún oṣù kẹta, ọdún 2026 (18-19, 2026), èyí tí yóò jẹ́ ìbẹ̀wò àkọ́kọ́ irú rẹ̀ tí olórí Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kan yóò ṣe sí UK ní ọdún mẹ́tàdínlógójì.
Gẹ́gẹ́ bí ìkéde láti ọ̀dọ̀ ìdílé Ọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lórí ìkànnì X wọn, @RoyalFamily, Ààrẹ Tinubu yóò wà pẹ̀lú ìyáàfin Àkọ́kọ́, Sẹ́nétọ̀ Oluremi Tinubu, àti pé Ọba Charles Kẹta àti Ayaba Camilla yóò gbàlejò rẹ̀ ní Windsor Castle.
Ìbẹ̀wò ìtàn náà yóò ṣàfihàn àjọṣepọ̀ ìjọba tó wà láàárín Nàìjíríà àti United Kingdom, ó sì fi ìbáṣepọ̀ tó ga jùlọ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè méjèèjì hàn ní gbogbo ìṣèlú, ọrọ̀ ajé àti àṣà.
A ní ìrètí pé ìbẹ̀wò Ààrẹ Tinubu yóò mú kí àjọṣepọ̀ Nàìjíríà àti UK lágbára sí i, pàápàá jùlọ ní àwọn agbègbè ìṣàkóso, ìṣòwò, ìdókòwò, àjọṣepọ̀ ààbò àti ìgbésẹ̀ ojúọjọ́, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun pàtàkì ètò ìṣèlú òkèèrè ti Nàìjíríà.
Comments are closed.