Ilé Iṣẹ́ Ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Ṣe Àwárí Ibùba Òògùn Olóró Ni Ilú Ìbàdàn, Gba Onírúurú Ìdì Òògùn Tó Lòdì Si Òfin
Ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tí ṣe àwárí ibùba tí afurasí ọdaràn n gbe oògùn olóró pamọ́ sí ni ìlú Ìbàdàn, nígbà tí wọn sì rí onírúurú òògùn olóró gbà.
Gẹ́gẹ́ bí Alukokoro ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, DSP Olayinka Ayanlade ṣe ṣàlàyé nínú àtẹ̀jáde tó fi ṣọwọ́ sí àwọn oníròyìn, pé ìròyìn tó dé sí etígbọ̀ọ́ ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá fihàn pé, ọkùnrin kan ti orúkọ rẹ n jẹ Oluwadamilare Adedayo n lo ilé kan ni òpópónà Abanise, ni agbègbè Academy, Olomi, ni ìlú Ìbàdàn láti fi àwọn òògùn olóró pamọ́ sí.
Látàrí ìròyìn yìí ni ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá ṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwádìí inú ilé náà àti agbègbè rẹ̀, nínú èyí tí wọ́n rí ìdì òògùn olóró indian hemp mẹ́sàn án (9), ìdì Canadian Loud mọ́kànlélọ́gọ̀rún (101), àti àwọn òògùn olóró míràn, eléyìí ti ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá gbà lójúnà àti pagi dínà pínpín òògùn olóró káàkiri ní agbègbè náà.
Nítorí àwárí ibùba yìí ni Ọ̀gá Ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Femi Haruna ti pàṣẹ fún àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ láti se àwárí afurasí náà kí o lè fi ojú wi iná òfin. Nígbà tó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọ̀gá àgbà Ọlọ́pàá ni orilẹ èdè Nàìjíríà, Kayode Egbetokun fún àtìlẹ́yìn rẹ̀ ni gbogbo ìgbà, o tún dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ilé iṣẹ́ aláàbò yòókù àti gbogbo àwọn tí ọ̀rọ̀ náà kàn, eléyìí tí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ wọn jẹ́ kí iṣẹ́ ìwádìí náà yọrí sí rere.
Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ fi dá àwọn ènìyàn rere Ìpínlẹ̀ náà lójú pé òun kò ní jáwọ́ láti máa dojú ìjà kọ ìwà ọ̀daràn ni gbogbo ọ̀nà, nígbà tó ke sí àwọn ará ìlú láti túbọ̀ máa pèsè ìrànlọ́wọ́ fún ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá nítorí pé ètò ààbò jẹ́ ojúṣe Gbogbo ènìyàn.
Abiola Olowe
Ìbàdàn