Take a fresh look at your lifestyle.

Oshodi Fí Ìdùnnú Rẹ̀ Hàn Lórí Ìṣọ̀kan Ilẹ̀ Áfíríkà Nípasẹ̀ Tẹ́nìsì Orí Tábìlì ‎

109

Bí ìdíje tẹ́nìsì orí tábìlì tilẹ̀ Áfríkà 2026 (ITTF Africa Cup 2026) ṣe bẹ̀rẹ̀, Ààrẹ Ẹgbẹ́ Tẹ́nìsì Orí Tábìlì ti Áfíríkà (ITTF Africa), Wahid Enitan Oshodi, ti yin ìdíje náà ní Libya gẹ́gẹ́ bí ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì kan tó kọjá eré ìdárayá, tó ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àmì agbára ìṣọ̀kan ilẹ̀ àti onírúurú.


‎Oshodi, tó tún jẹ́ Igbákejì Ààrẹ Àgbà ti Tẹ́nìsì Orí Tábìlì Àgbáyé (International Table Tennis Federation ITTF), yin ìjọba àti àwọn ènìyàn Libya fún ìdúróṣinṣin wọn láti gbàlejò ọ̀kan lára àwọn ìdíje pàtàkì ti àjọ náà.

Comments are closed.

button