Alaga ati Alakoso fun àwọn Ọmọ Orílè-èdè Nàìjíríà ní oke òkun (NiDCOM), Abike Dabiri-Erewa, ti so ibanuje jijinle lori iku ti Khaleed Oladipo, omo ile iwe Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ọmọ ogún ọdún ti won fi ọ̀bẹ pa ni Leicester, United Kingdom.
Khalid, omo ile iwe ẹ̀tò ààbò ayelujara ọdún keji ni fásítì De Montfort, ni wọn royin wí pe wọn kọlù nigba ti o n pada si ile lati wo ere bọọlu afẹsẹgba kan.
Àwọn Ebi re wiy pe o jẹ ọmọ ti wọn féràn gidigidi sùgbón ti wọn ti da emi re kuru báyìí
Dabiri-Erewa se apejuwe ìṣẹlẹ náà gégébí ohun ti o bani ninu jey, o si so wí pe ó jẹ pipadanu ìrora fun idile Oladipo ati awon ara ilu Naijiria ni ile ati ni awon ajeji.
Ó ke si awon alase Orílẹ̀-èdè UK lati se iwadii kikun ati ri daju wí pe wọn da ododo fun oloogbe naa, nigba ti o tun fi idi ifaramo NiDCOM si alafia ati ààbò awon ọmọ Nàìjíría ti wọn ngbe ni okeere mule.