Ilé iṣẹ́ Ọlópàá Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti kéde fún gbogbo aráàlú pé wọ́n ti ṣàṣeyọrí láti dóòlá ẹnìkan tí a jí gbé lọ́wọ́ àwọn ajinigbé.
Ẹni tii se Alukoro ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, DSP Ayanlade Olayinka ló fi ọ̀rọ̀ yìí lédè nínú àtẹ̀jáde kan to fi ṣọwọ́ sí àwọn akọ̀ròyìn nínú èyí tó ti sọ di mímọ̀ pé ilé iṣẹ́ náà gbà ìpè pàjáwìrì kan lọ́wọ́ arábìnrin Alimot ni agbègbè Ojongbodu, ní aago méjì kọjá ìṣẹ́jú mẹ́wàá òru (02:10) ní ọjọ́ kẹrìnlélógún (24) oṣù Kínní, ọdún 2026.
Alimot ló fi tó ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá létí pé àwọn ajinigbe ti wọn di ìhámọ́ra ogun ti jí Haruna Lawal to n gbe ni agbègbè Olorunda ni òpópónà Ọ̀yọ́ gbé, ti wọn sì gba kẹ̀kẹ́ alúpùpù rẹ̀ lọ sí ibi tí ẹnìkan kò mọ̀.
Àtẹ̀jáde náà jẹ́ kó di mímọ̀ pé lọ́gán tí ìròyìn ijinigbe náà dé sí etígbọ̀ọ́ ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá ni Ọ̀gá Ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Haruna Olufemi ti ké sí àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ láti lọ sí agbègbè náà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, eléyìí tó mú kí àwọn ajinigbe náà fi ẹni tó wà ní ìgbèkùn wọn sílẹ ti wọn sì sálọ nígbà tí wọn gburó pe àwọn Ọlọ́pàá ti sun mọ́ wọn.
DSP Ayanlade ṣàlàyé nínú àtẹ̀jáde náà pé arákùnrin tí wọ́n jí gbé náà fara pa ní orí lásìkò ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣùgbọ́n ti ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá ti gbé lọ sí ilé ìwòsan níbi to ti n gba ìtọ́jú lọ́wọ́lọ́wọ́.
Komíṣọ́nà Ọlópàá Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Haruna Olufemi dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọ̀gá àgbà Ọlópàá ni Orílè èdè Nàìjíríà Kayode Egbetokun fún ìtọ́sọ́nà ọgbọ́n, àti àtìlẹ́yìn rẹ̀ ni gbogbo ìgbà. Kọmíṣọ́nnà náà tún gbé oríyìn fún àwọn ọlọ́pàá fún ìwà akíkanjú àti àwọn ọmọ iṣẹ́ tí wọ́n kópa nínú iṣẹ́ náà, láì yọ gbogbo àwọn tó lọ́wọ́ sí àṣeyọrí iṣẹ́ náà silẹ̀.
Nígbà tí ilé iṣẹ́ Olópàá jẹ́ kó di mímọ̀ pé akitiyan láti tọ́pa àti mú àwọn afurasí tó sá lọ náà n tẹ síwájú, wọn fi dá ará ìlú lójú pé wọ́n dúró ṣinṣin láti rí i dájú pé àwọn ọ̀daràn kò rí ibi ìfarapamọ́ kankan ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, wọ́n sì ń rọ̀ gbogbo ènìyàn láti tẹ̀síwájú nínú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹlú ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá nípa pípèsè ìròyìn tó péye lásìkò.
Abiola Olowe
Ìbàdàn