Take a fresh look at your lifestyle.

Àwọn Ọmọ Ẹgbẹ́ Gúúsù Nìkàn Ló L’ẹ̀tọ́ Láti Díje Fún Ipò Ààrẹ – PDP

79

Ẹgbẹ́ Òṣèlú People’s Democratic Party (PDP) ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Ààrẹ tẹ́lẹ̀ Goodluck Jonathan àti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ mìíràn láti Gúúsù Nàìjíríà nìkàn ló l’ẹ̀tọ́ láti díje fún ipò Ààrẹ lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú náà nínú ìdìbò gbogbogbòò ti ọdún 2027.

‎ Alága gbogboògbò tí ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, Ambassador Tanimu Turaki ṣàlàyé nígbà tó ń bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ìpàdé tí wọ́n ṣe pẹ̀lú Igbákejì Ààrẹ Nàìjíríà tẹ́lẹ̀, Mohammed Namadi Sambo, ní ilé rẹ̀ ní Abuja.

‎Turaki sọ pé ìbẹ̀wò náà jẹ́ ara ìgbìmọ̀ gbogbogbòò láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí tuntun tí wọ́n yàn ní ẹgbẹ́ náà níbi Àpérò Ìdìbò àpapọ ti PDP tí wọ́n ṣe ní Ibadan.

Comments are closed.

button