Take a fresh look at your lifestyle.

Ìpínlẹ̀ Rivers Yoo Tubọ Tẹpẹlẹ Mọ Ètò Ààbò

141

 

Ìpínlẹ̀ Rivers ti fi dá àwọn èniyàn rẹ̀ lójú pé àwọn yóò tubọ tẹpẹlẹ mọ́ ètò ààbò ẹ̀mí àti dúkìá wọn káàkiri gbogbo agbègbè náà.

 

Alábójútó ipinlẹ Rivers, Vice Admiral Ibok-Ete Ibas tó ti fẹ̀yìntì nìdí isẹ́ ológun ló sọ èyí níbi ìpàdé gbọ̀ngàn ní olú ilu iwọ oòrùn ijọba ìbílẹ̀ Ahoada ní ìpínlè náà ti Kọmísọ́nà àgbà àwọn Ọlọ́pàá, Olugbenga Adepoju sojú fún . Ó fi léde pe ètò ààbò ló jẹ àkọ́kọ́ lọ́kàn wọn ní ọnà láti jẹ kí àlàáfíà jọba, kí àwọn ènìyàn sì máa tawọ́n lólobó ní àsìkò láti leè ràn àwọn agbófinro lọ́wọ́ fún iṣẹ wọn.

 

Kọmísọ́nà àgbà àwọn Ọlọ́pàá, Olugbenga Adepoju tún rọ àwọn adarí agbègbè, ẹgbẹ àwọn ọ̀dọ́ àti ti àwọn Obìnrin àti àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ láti sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ijọba kí àlá wọn leè di mímu ṣẹ.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button