Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Tinubu Yóò Wà Níbi Ìfinijoyè Pope Leo Ẹ̀lẹ́ẹ̀kẹrìnlá

130

Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Naijiria, Bola Ahmed Tinubu yóò kúrò ní Abuja lọ sí Rome ti ṣe Olu ìlú Italy ní ọjọ́ Àbámẹ́ta láti jẹ ìpè ti wọ́n pèé fún ayẹyẹ Ìfinijoyè Pope Leo Ẹ̀lẹ́ẹ̀kẹrìnlá.

Pope Leo Ẹ̀lẹ́ẹ̀kẹrìnlá tile sọ pé òun nífẹ̀ẹ́ orílè-èdè Nàìjíríà àti pé òun ti ṣe iṣẹ́ Iransẹ fún Ọlọ́run ní ìjọ Apostoliki Nunciature ní ìlú Èkó ní nǹkan bí ọdún 1980.

“Orílè-èdè gíga Nàìjíríà ṣe pàtàkì sí mi, mo ti ṣe Iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún Ọlọ́run ní ìjọ Apostoliki Nunciature ní ìlú Èkó ní nǹkan bí ọdún 1980“.

Àwọn ti yóò bá ààrẹ kọ̀wọ́ rìn bí ibùjòkó ààrẹ ṣe sọ ní, Mínísita fún ilẹ̀ òkèèrè, Ambassador Bianca Odumegwu-Ojukwu, àwọn Bísọ́ọ̀bù àgbà ti Owerri ati ààrẹ ìjọ Kátólìkì Conference Ilẹ̀ Nàìjíría, Lucius Ugorji, Ignatius Kaigama ti Abuja, àti Alfred Martins ti Eko. Pẹlu Kátólìkì Bísọ́ọ̀bù ti Díósísì Sokoto, Mathew Hassan Kukah.

Ayẹyẹ Ìfinijoyè Pope Leo Ẹ̀lẹ́ẹ̀kẹrìnlá yóò wáyé ní ọjọ́ kejìdínlógún ní St. Peter’s Square ní Vatican.

Àwọn afọbajẹ póòpù yàán lẹ́yìn Ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n ti Pope Francis wàjà ní ọjọ́ kọkànlélógún, oṣù kẹrin ọdún 2025. Ààrẹ Tinubu yóò padà sí Abùjá ní ọjọ́ ìṣẹ́gun oṣù karùn ún Ogúnjọ́, ọdún 2025.

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button