Take a fresh look at your lifestyle.

Ìjọba Ìpínlẹ Kaduna Àti Àjọ UNICEF Fọwọ́sowọ́pọ̀ Láti Gbógunti Àìsàn Ìgbóná

65

Ìjọba Ìpínlẹ Kaduna pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Àjọ UNICEF tí ń gbé ìgbésẹ̀ akin láti gbógunti ìtànkálẹ̀ àìsàn ìgbóná èyí tí ó ti sekúpa àwọn ọmọdé méjì ní Ìpínlẹ̀ Kaduna

 

Àìsàn náà, èyí tí ó súyo ní Unguwan Kanawa, ní ìjọba Ìbílẹ̀ Zaria ni ó ti fi ọwọ́ ba àwọn ògo wẹẹrẹ tí ó tó ogún. Ìròyìn míràn fi yéwa pé àwọn ògo wẹẹrẹ mẹ́fà ni ó ti pàdánù ẹ̀mí wọn

 

Ìtànkálẹ àrùn náà wáyé látàrí kíkùnà àwọn òbí láti gba abẹ́rẹ́ àjẹsára fún àwọn ọmọ wọn látàrí àgbọ́yé òdì nípa ètò àjẹsára, níbi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdílé ti fi ara káásá àrùn náà. Ìjọba Ìpínlẹ̀ Kaduna ti ń gbé ìgbésẹ̀ ní kíákíá láti rí i dájú pé gbígba abẹ́rẹ́ àjẹsára náà kárí-ilé-kárí-oko ní Ìpínlẹ̀ Kaduna

 

 

Comments are closed.

button