Take a fresh look at your lifestyle.

10

Aṣọ Ológun Tí Àwọn Ènìyàn Kan Ńwọ̀ Lòdì Sí Ètò Ààbò – Ológun Ṣe Ìkìlọ̀

Awọn ọmọ ológun orílè-èdè Nàìjíríà tí rọ àwọn olùgbé orílẹ̀-èdè yìí láti yàgò fún wíwọ aṣọ ológun wọn láì se ọmọ ológun Nàìjíríà nitori ṣíṣe èyí a máà tàbùkù bá ìyí àwọn ọmọ Ológun, a sì máa mú kí ètò ààbò bẹ́ rẹ́lẹ̀.

Nígbàtí ó ń sọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwọn oníròyìn tó si mọ́ àwọn ọmọ ológun ní Abuja, ọ̀gágun àgbà, Gold Chibuisi sọ pé lílo aṣọ Ológun ní àìtó tàbùkù bá òfin orílè-èdè yii, o tún fi ààyè gba àwọn arúfin láti ṣe iṣẹ ibi wọn.

“Ó yà mi lẹ́nu pé bí a ti ń kìlọ fún àwọn ènìyàn tó, ìṣẹ̀lẹ̀ wíwọ aṣọ ológun sì tún ń ṣẹlẹ̀.
“Ó lòdì si Òfin Nàìjíríà.
“Bóyá o nífẹ̀ẹ́ síi láti máà wọ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, wíwọ aṣọ ologun wa èèwọ̀ ni.
” Ti o bá ní ìfẹ́ sí isẹ́ ológun, lọ forúkọsílẹ̀ kó sì lọ darapọ̀ mọ́ wọn. Máṣe wọ asọ wà ti o kò bá ṣe ara wa. Ó sọ èyí.
 Àwọn tó bá rú òfin yìí, wọn a fojú bá ilé ẹjọ́.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn arúfin ló ń lo aṣọ ológun láti dá ọran. O ṣòro látí dá ológun mọ̀ tàbí ẹni ti kí ṣe ológun, ọ̀gágun Chibuisi sọ síwájú.

Ó wá rọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdílé àti àwọn agbègbè láti ta àwọn ènìyàn jí nípa èyí, kí wọn sọ fún àwọn tó ń ṣe bè láti má ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́.

Ọ̀gágun àgbà Chibuisi sọ pé a kọ́ Ológun láti mú àwọn ènìyàn tó ń wọ asọ ologun laiṣe ọmọ ológun kí wọn sì fàwọ́n lé àwọn Ọlópàá lọ́wọ́ fún iwadi àti ìyà tó tọ́ sì wọn ní.
” Èyí to wá pẹ̀lú rẹ̀ bíi ìfipámúni láì dára, ọrọ òdì sí arúfin abbl, eyi kò dára, àwa náà mọ bẹ́ẹ̀.

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button