Àjọ UNICEF ti ké sí ìjọba Ìpínlẹ̀ Kano láti gbé ìgbésẹ̀ ní kíákíá lójúnà àti dènà àrùn rọ́pa-rọsẹ̀ látàrí bí àrùn náà se súyọ ní ìpínlẹ̀ Kano
Asojú Àjọ náà ní Ìpínlẹ̀ Kano, Rahma Farah ni ó rawọ́ ẹ̀bẹ̀ níbi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ lórí àrun rọpá-rọsẹ̀ tí ó wáyé àti àjẹsára gbogbo ìgbà síwájú ọ̀sẹ̀ àyájọ́ Abẹrẹ́ Àjẹsára ti àgbáyé
Ìfikùnlukùn náà wáyé pẹ̀lú ìjọba Ìpínlẹ̀ Kano àti Ìgbìmọ̀ Ilé ìwòsàn Alábọ́dé ní Ìpínlẹ náà láti se ìkéde tí yóò kẹ́sejárí kí àwọn ará ilu le è kópa nínú eto àbẹ́rẹ́ àjẹsára tí yóò wáyé láàrin ọjọ́ kẹrìnlélógún sí ọgbọ̀n ọjọ́ osù kẹrin ọdún 2025 èyí tí yóò se déédé pẹ̀lú àyájọ́ ọ̀sẹ̀ àjẹsára ti àgbáyé