Take a fresh look at your lifestyle.

Eid-el-Fitri: Makinde Ba Musulumi Yọ Ayọ Ọdún Ramadan

98

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde ti ba gbogbo Musulumi jákèjádò Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ àti Orilẹ Èdè Nàìjíríà lápapọ̀ yayọ Eid-el-Fitri 2025.

Makinde, nínú àtẹ̀jáde ti Amugbalẹgbẹ fún Gómìnà lórí ìròyìn, Suleimon Olanrewaju fi síta lo kí gbogbo musulumi kú àgbàyọrí Ramadan ti ọdún yìí nígbà tó tún lù wọ́n lọgọ ẹnu fún ìfaradà, ìgbàgbọ́, ẹbọ wọn àti ìgbẹ́kẹ̀lé wọn nínú Allah ni gbogbo àsìkò oṣù Ramadan, O wá gbà wọ́n níyànjú láti di ẹkọ ti wọn kọ ni àsìkò náà mú ṣinṣin.

Bákan náà ni Gómìnà tún rọ gbogbo wọn láti túbọ̀ máa gbaruku ti ìjọba ni gbogbo ẹ̀ka kí Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lè máa jẹ igbadun ìṣọ̀kan nínú ẹ̀sìn síwájú síi.

Gómìnà fi dá wọn lójú pé ìṣèjọba òun yóò tẹ síwájú láti máa fi ohun tó jẹ wọn lógún ṣáájú ohun gbogbo ati láti mú itẹsiwaju dé bá Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. O wá fi yé wọn pé eléyìí ko ni le ṣeéṣe láìsí ìṣọ̀kan àti ìfaradà.
O wá ki gbogbo Musulumi jákèjádò ku ọdún.

Abiola Olowe
Ìbàdàn

Comments are closed.

button