Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Èkó Pé Gómìnà Sanwo-Olu Láti Fọwọ́ Ọ̀kúnkúndùn Mú Ọ̀rọ̀ Àwọn aAjírin Àti aAṣarin Lójú Pópó
Pẹ̀lú ìgbésẹ̀ láti fi dáàbò bo àwọn nǹkan ìní ìjọba àti ààbò àwọn ará ìlú lójú pópó, Ilé Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Èkó ti rọ Gómìnà Sanwo-Olu láti pàṣẹ fífi ọwọ́ ṣìnkún òfin mú àwọn olè akólè lójú pópó tí kò bá òfin mu.
Ilé Aṣòfin náà nínú ìpinnu wọn fẹnu kò pé, kí Gómìnà Sanwo-Olu pàṣẹ fún Alákóso àgbà fún Ọ̀rọ̀ Àyíká Àti Omi láti fi òfin àmójútó àyíká ọdún 2017 múlẹ̀, kí wọ́n sì gbé Ìgbésẹ̀ ìfìyàjẹ tó tọ́ fún àwọn ẹ̀sùn tó níí ṣe pẹ̀lú ìwà kíkó ìdọ̀tí lójú pópó àti àwọn ọmọlanke akólẹ̀ tí kò bófin mu ní Ìpínlẹ̀ yìí.
Bákan náà ni wọ́n rọ àwọn agbófinró láti máa fọwọ́ òfin mú àwọn tí wọ́n ń lọ́wọ́ nínú olè jíjí àwọn irin ojú ọ̀nà àti àwọn nǹkan ìní ìjọba mìíràn.
Lára ìfẹnukò wọn náà ni pé, kí ilé-iṣẹ́ ìjọba Ìpínlẹ̀ Èkó fún Ọ̀rọ̀ Àyíká Àti Omi láti fi òfin àmójútó àyíká ṣàmúlò abala kẹ́rìndín-lọ́gọ́ta àti ìkẹ̀talé-lọ́gọ́ta òfin ọdún 2017 tó níí ṣe pẹ̀lú kíkó ìdọ̀tí bí àwọn tó níí ṣe pẹ̀lú irin, èyí tí wọ́n fi fòfin de kíkó àwọn ohun èlò ìdọ̀tí lọ́nà àìtọ́ àti fífi ọwọ́ òfin mú àwọn tó ń fi ohun èlò ìdọ̀tí ṣe òwò láìgbà ìwé àṣẹ lọ́wọ́ ìjọba.
Ìgbésẹ̀ yìí ló tẹ́lẹ̀ àbá Aṣòfin Gbọ́láhàn Yishawu ti ọ̀pọ̀ àwọn aláṣẹ àti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ fọwọ́ sí i.
Nínú àbá rẹ̀ náà, Aṣòfin Yishawu sọ pé, “pẹ̀lú ìlàkàkà ìjọba Ìpínlẹ̀ yìí láti pèsè àwọn ohun amáyédẹrùn àti ohun ìdàgbàsókè ìlú, kò yẹ kí àwọn ọ̀bàyéjẹ̀ kán máa fa ọwọ́ ìjọba sẹ́yìn. Àti pé, inú ilé Aṣòfin náà kò dùn, kí sì ìjọba tété fọwọ́ ọ̀kúnkúndùn mú ọ̀rọ̀ wọn.”
Bákan náà ni wọ́n pe, Ìlé-iṣẹ́ Ìjọba fún Ọ̀rọ̀ Ìròyìn, Ìkéde àti Ọgbọ́n-ìṣèlú láti ṣàgbékalẹ̀ àwọn atanilólobó tí yóò tètè máa fi ọ̀rọ̀ náà tó àwọn aláṣẹ létí, tí wọn yóò fi lè máa mú àwọn olè ajírin lójú pópó, kí wọ́n sì rọ àwọn ará ìlú láti máa ṣe iṣẹ́ ojú laláákàn fi ń ṣọ́rí láàárín ara wọn láti fi lè máa dáàbò àwọn ohun ìdàgbàsókè ìlú yìí.
Lẹ́yìn tí gbogbo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ilé Aṣòfin náà tí sọ̀rọ̀ lórí kókó ọ̀rọ̀ náà, ní wọ́n tó fẹnu kò, tí ó fi di ìpinnu Ilé Aṣòfin náà.
Láńre Lágada-Àbáyọ̀mí