Igbákejì Ààrẹ Kashim Shettima ṣe àbẹ̀wò sí ìpínlẹ̀ Jigawa, Àríwá-Iwọ̀ oòrùn Nàìjíríà.
Ó gbéra láti ṣèkẹ́dùn pẹ̀lú Gómìnà Umar Namadi lórí ikú ìyá àti ọmọ rẹ̀.
Ajalu meji lo de ba Gomina naa nigba ti o padanu iya rẹ, Hajiya Maryam ni ọjọ ọdun Keresimesi, ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu kejila, ti agba ọmọkunrin rẹ, Abdulwahab, naa si tun jẹpe ọlọrun ni ọjọ kẹrindin-lọgbọn oṣu kejila.
Abdulwahab ẹni ọdun mẹrinle-logun padanu ẹmi rẹ ninu ijamba mọto ni Ọjọbọ.
Igbakeji Aarẹ Shettima kuro ni Maiduguri lọ si Jigawa ni ọjọ Abamẹta ni deede agogo kan ọsan ku iṣẹju mẹẹdọgbọn, ti Gomina ipinlẹ Borno Ọjọgbọn Babagana Zulum ati awọn to tun sunmọ si tẹle.
Igbakeji Aarẹ ti wa ni ipinlẹ Borno lati ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹrinle-logun, oṣu kejila, fun isinmi ọdun Keresimesi.