Take a fresh look at your lifestyle.

Lórí Ọ̀rọ̀ Abẹ́rẹ́ Àjẹsára Àwọn Ohun Ọ̀sìn, Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ogun Pè Fún Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Àwọn Adaran, Òsìṣẹ́ Elétò Ìlera Ohun Ọ̀sìn

178

Akọ̀wé àgbà fun ẹka ètò ọ̀gbìn ni ìpínlẹ̀ Ogun, Arábìnin Kehinde Jokotoye ti pè fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ láàrin àwọn adaran àti àwọn alámòjútóó nípa ìlera ohun ọ̀sìn fún ìkẹ́sẹjárí ètò abẹ́rẹ́ àjẹsára fún àwọn ohun ọ̀sìn èyí tí ó ń lọ lọ́wọ́

 

Ó pe ìpè náà nígbà ti o n gba àlejò ẹgbẹ́ àwọn Fulani daran-daran, Alhaji Usman Bello, ní ọ́ọ́fìsì rẹ èyí ti o wà ní Oke Mosan, ilu Abẹokuta, ní ọjọ́ Ẹtì

 

Jokotoye sàlàyé pàtàkì ètò náà láti dènà àrùn eyi ti o n ja káàkiri látàrí ìwọlé àti ìjáde àwọn ẹran èyí tí ó ń wáyé lásìkò tí a wà yí. Ó fìdí ọrọ múlẹ̀ pé abẹ́rẹ́ àjẹsara náà yóò dènà ìtànkálẹ̀ àrun èyí ti o le e kó wahala ba awọn ohun ọ̀sìn àti àwọn ènìyàn lápapọ̀

 

Comments are closed.

button