Ìgbákejì Ààrẹ Kashim Shettima sọ pé ayẹyẹ Maulud ní wọ́n fí n pé fún àtúnṣe ìpinnu fún àwọn alákóso ìjọba ní gbogbo ọ̀nà, bí ìjọba ṣé n gbìyànjú láti kojú àwọn ìṣòro tó ń kojú àwọn ọmọ Nàìjíríà.
O sọ̀rọ̀ náà ní ọjọ́ Àbámẹ́ta ní Abuja, níbí Ayeye ọdún kéjìdínlogoóji (38th) tí Maulud àpapọ̀ tí Shiekh Ibrahim Niass Alkaulakhy. O wà pẹ̀lú àwọn ẹẹkan bí Shiekh Muhammad Sanusi II, Sautul Faida Shiekh Dahiru Usman Bauchi Sheikh Ibrahim Saleh Alhusaini, Mínísítà fún ètò Ìṣúná àtí ètò ọrọ̀-àjé, Alàgbà Abubakar Atiku Bagudu, láàrín àwọn mìíràn.



Ayẹyẹ ọjọ́ìbí Anabi Muhammed ti ọdun yii je tí ọdún ìkejìdínlogóji (38th) èyí tí wọ́n fí ṣé ádùrá fún àlàáfíà àtí ìsọkan Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.