Take a fresh look at your lifestyle.

Àtúnṣe Odò Ńlá Dasin Hausa Ní Ìpínlẹ̀ Adamawa Yóò Tán Ìsòro Omíyalé- Ilé Ìgbìmọ̀ Asòfin Pàrọwà Sí Ìjọba Àpapọ̀

0 194

Ilé Ìgbìmọ̀ Asòfin Àgbà ti pàrọwà sí ìjọba àpapọ̀ láti se àtúnṣe Odò ńlá Dasin Hausa ní ìpínlẹ̀ Adamawa, lójúnà àti wá ojútùú sí ìsòro omíyalé ní Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà

 

Lára àwọn ọ̀nà tí yóò fi òpin sí ìsòro ẹ̀kún omi náà ní síṣe àtúnṣe odò ńlá Benue àti Niger, àti àwọn odò ńlá míràn tí ó já papọ̀ mọ́ odò Lagdo pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Orílẹ̀-èdè Cameroon.

 

Ilé ìgbìmọ̀ Asòfin gbé ìgbésẹ̀ náà láti wá ojútùú sí àbádòfin tí sẹ́nétọ̀ Binos Dauda Yaroe láti ìpínlẹ̀ Adamawa gbé jáde, èyí tí ó pèpè fún ọ̀nà àbáyọ sí ìsòro omíyalé láti ara sísí odò ńlá Lagdo ti Orílẹ̀-èdè Cameroon, èyí tí ó ń kó ìpalára bá ará ìlú ní gbogbo ìgbà.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button