Take a fresh look at your lifestyle.

Nàìjíríà Gbá Àwọn Ọmọ Rẹ̀ Ọgọ́rùn-Àti-Mẹ́jọ Látí Orílẹ̀-èdè Niger

0 391

Ìjọba Nàìjíríà tí gbá àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè ọgọ́rùn-ún àti mẹ́jọ [108] tí há mọ́ orílẹ̀-èdè Niger ní Pápá kọ òfurufú Murtala Mohamed International, ní Ìlú Èkó, Gúúsù Ìwọ̀-oòrùn Nàìjíríà.

Ipadabọ náà jẹ́ iṣẹ́ Ìjọba Àpapọ̀ ní Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Ajọ Àgbáyé fún Iṣipo (International Organization for Migration IOM).

Ọ̀gbẹ́ni Alexander Oturu, alabojuto àgbègbè Ìwọ̀-oòrùn tó ṣoju fún Kọmisọna Àgbà, Aliyu Ahmed, ṣàlàyé pé ní ìbámu pẹ̀lú Ètò Ìrètí Túntún tí Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu, àwọn wọnyí ní wọ́n yóò darapọ̀ mọ́ àwọn ètò ìjọba àpapọ̀, àwọn ètò isọdọtun tí Àjọ àgbáyé (UN) àtí tí Ilé-iṣẹ́ Iṣipo pàdà (IOM).

Gẹ́gẹ́ bí Ọ̀gbẹ́ni Oturu ṣé sọ́, Ọkùnrin Méjì lè lọgbọn 32, Obìnrin mọkandinlọgbọn 29, àwọn ọmọdé ogójì lé mẹ́rin 44 àti àwọn ọmọ ìkókó mẹ́ta 3 ló wà nínú ọkọ òfurufú náà.

Ilé-iṣẹ́ Ìtọjú Pajawiri ní ìpínlẹ̀ Èkó ló gbá wọ́n sì ìbùdó kí NCFRMI àti IOM tó ní àdéhùn ipin-mẹta láti pèsè ibùgbé fún ìgbà díẹ fún wọ́n ṣáájú ki wọ́n tó fún wọ́n ní owó ọkọ láti lọ́ sí ibùgbé oníkálukú wọ́n.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button