Take a fresh look at your lifestyle.

Ìgbákejì Ààrẹ Naìjírìà Balẹ̀ Sí Orílẹ̀-èdè China

0 263

Ìgbákejì Ààrẹ Naìjírìà, Kashim Shettima tí balẹ̀ sí Olú-ìlú Orílẹ̀-èdè China, Beijing láti ṣé ojú Ààrẹ Bola Tinubu níbí ìpàdé tí yóò wáyé láti ọjọ́ kẹ́rindìnlógun (16th-18th) sí ọjọ́ kejidinlogun tí wọ́n pé àkọlé rẹ̀ ní ‘High-quality Belt and Road Cooperation: Together for Common Development and Prosperity.’

Ìgbákejì Ààrẹ Nàìjíríà náà yóò darapọ̀ mọ́ àwọn akẹgbẹ rẹ̀ káàkiri àgbáyé láti Africa, Asia Europe àti Latin America níbí àpérò náà, ẹlẹẹkẹwaa irú rẹ̀ èyí tí Ààrẹ Orílẹ̀-èdè China, Xi Jinping ń ṣé àtìlẹ́yìn fún.


Ìgbákejì Ààrẹ náà yóò ní ànfààní láti ṣé ìpàdé pẹ̀lú àwọn Ààrẹ àti aṣojú àwọn Orílẹ̀-èdè mìíràn láti ṣé igbelarugẹ ìlànà ìṣòwò tí Orílẹ̀-èdè Naìjírìà ní ìbámu pẹ̀lú ìdàgbàsókè ọrọ̀-ajé tí ìṣàkóso Ààrẹ Tinubu.

Lára àwọn tó kí igbákejì Ààrẹ náà káàbọ̀ ní Pápá Kọ̀ Òfurufú Beijing International Airport ní Baba Jidda tó jẹ́ aṣojú Naìjírìà ní China, ìgbákejì alága ìgbìmọ̀ tí ‘Beijing Municipal People’s Congress’ Mr Li Yingpin àti ìgbákejì Olùdarí ètò àwọn ọmọ Ilẹ̀ Adúláwọ̀ ní China, Mr Yu Yong.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button