Take a fresh look at your lifestyle.

Orílẹ̀-èdè Eswatini Yayọ̀ Àrùndínlọ́gọ̀ta Ọdún Tí Wọ́n Gba Òmìnira

0 190

 

Ọba Eswatini fò fàyọ̀ ní ọjọ́ Ọjọ́rú látàrí ọdún márùndínlọ́gọ̀ta tí wọn gba Òmìnira .

Ọba Mswati III ti Eswatini ni wọ́n rí tó ń yan fanda fanda láàrín àwọn ènìyàn níbi tó ti ń sàjọyọ̀ ayẹyẹ ọdún òmìnira pẹlú wọn ní pápá ìṣeré àpapọ̀ ti Somhlolo ni Lobamba.

Bí ó ti bá àwọn ènìyàn rẹ̀ sọ̀rọ̀, ó wí pé àlàáfíà ti wọ́n mọ ilẹ̀ Áfíríkà mọ́ ló yẹ kí wọ́n máa lépa, kò yẹ ki ìdàrúdàpọ̀ máa wá pàápàá jù bí èyí tí ó ń ṣẹlẹ̀ ní Àríwá Adúláwọ̀ báyìí látàrí ìdìtẹ̀gbàjọba tó ń wáyé lemọ́lemọ́.

Lára àwọn adari tó wá síbi ayẹyẹ náà ni ààrẹ orílẹ̀-èdè Taiwa, Tsai Ing-wen to bẹ̀rẹ̀ àbẹ̀wò ọlọ́jọ́ mẹ́rin ní ọjọ́ ìṣẹ́gun.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button