Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti san ajesile owó tí ìjọba n yọ lórí owó oṣù àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ni Ìpínlẹ̀ náà
Eleyii ló wà ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí tí Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde ṣe fún Àgbáríjọ Ẹgbẹ́ Òṣìṣẹ́ sí pé òun yíò san ajesile owó wọn pẹ̀lú owó oṣù kẹjọ ọdún yìí.
Gẹ́gẹ́ bí Kọmísánnà fún Iroyin àti Ìlanilọ́yẹ, Dọtun Oyelade ṣe ṣàlàyé pé, Gómìnà Makinde ti ya owó tó lè diẹ ní Bílíọ̀nù kan Náírà (₦1.3bn) láti san ajesile owó tí ìjọba ti yọ nínú oṣù Kẹfà, Ikeje àti oṣù Kẹjọ.
Gómìnà wá jẹ kó di mímọ̀ fún gbogbo òṣìṣẹ́ to bá fẹ láti máa fi owó pamọ́ sí àsùwọn Alajesẹku (Cooperative Contributions) lati ṣe bẹẹ pẹlú ẹgbẹ́ oṣiṣẹ nítorí pe ijoba ko ni lọwọ sí yíyọ owó pamọ́ láti inú owó oṣù wọn.
Abiola Olowe
Ìbàdàn
Leave a Reply