Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Tinubu Yóò Búra Fún Àwọn Mínísítà Ti Ọ Yan Ni Ọjọ́ Ajé.

0 217

Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu yóò ṣe Ìbúra wọlé sí ẹnu iṣẹ ni ọjọ́ ajé ọjọ́ kankànlélógún oṣù kẹjọ fún àwọn Mínísítà Tuntun èyí tí o Yan sílẹ̀.

Èyí yóò wáyé ni ilé iṣé ìjọba tó wà ní ìlú Abuja.

Ààrẹ ti fi orúkọ àwọn Mínísítà ránṣẹ́ ni ọjọ́rú  sí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin, ni èyí tí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin  bù wọn Lu.

Akọ̀wé àgbà fún ilẹ iṣé ìjọba, Nnamdi Mbaeri lo sọ èyí di mímọ̀, O ni ago mẹwàá òwúrọ̀ ni ìbúra náà yóò wáyé.

Ó ni ki wọn rí wí pé gbogbo àwọn ìwé erí ati èsì ìdánwò pátápátá láti ilẹ ìwé ni o pé sí wọn lọ́wọ́, o ni láti agọ mẹwàá sí mẹ́rin irọlẹ ni fi wáyé.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button