Orílẹ̀-èdè Benin tí tẹnumọ pé ìbaráẹnísọ̀rọ látí wá ojútùú sí rògbòdìyàn náà jẹ́ òun tí òún fẹ́ jùlọ sí ìfipágbàjọba àwọn Ológun Orílẹ̀-èdè náà.
Mínísítà ilẹ̀ òkèèrè tí orílẹ̀-èdè náà, Olushegun Adjadi Bakari, sọ fún àwọn òníròyìn pé orílẹ̀-èdè rẹ̀ ń bèèrè ìtúsilẹ̀ Ààrẹ Bazoum àtí gbígbé ìjọba pàdà lè lọ́wọ́.
Bakari tún jẹrìí àtìlẹ́yìn kikùn fún àwọn àkitiyan ẹgbẹ́ ìwọ̀-oòrùn Áfíríkà ECOWAS látí yanjú áàwọ̀ tó ń lọ́ lọ́wọ́ náà.
Oríṣiríṣi àwọn Orílẹ̀-èdè Ìwọ̀-oòrùn Áfíríkà, pẹ̀lú Senegal, tí ṣé ìlérí látí fí àwọn ọmọ ogún ránṣẹ́ tí ẹgbẹ́ náà bá tí ṣetán látí jà.
Àdári àwọn ọmọ ogún tó dìtẹ gbàjọba náà, Orílẹ̀-èdè Mali àtí Burkina Faso náà tí ṣèlérí látí kojú irú ìgbésẹ̀ bẹ̀ẹ́.
Leave a Reply