Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko labẹ Oludari Ile, Aṣofin Mudashiru Ọbasa bẹrẹ ayẹwo orukọ awọn alakoso-agba ti Gomina Babajide Sanwo-Olu fi ranṣẹ si Ile Aṣofin naa.
Ile Igbimọ Aṣofin yii fẹnu ko lati ṣagbekalẹ igbimọ ṭẹẹkoto ti yoo ṣiṣẹ ayẹwo awọn eniyan ti wọn fẹ gba ipo alakoso agba laarin Ipinlẹ yii naa. Oludari Ile Aṣofin naa, Aṣofin Mudashiru Ajayi Ọbasa darukọ awọn ọmọ ẹgbẹ igbimọ tẹẹkoto naa, eyi ti Aṣofin Fatai Mojeed jẹ Alaga wọn, ti wọn yoo jabọ pada fun Ile laipẹ.
Ẹwẹ, awọn ọmo ̣ẹgbẹ aṣofin kan ṣaroye pe, ko si aṣoju lati awọn agbegbe kan ni ipnlẹ yii ninu awọn orukọ naa, bẹẹ ni awọn kan ṣaroye pe, ko si awọn orukọ kankan lati awọn agbegbe ijọba ibilẹ ninu orukọ naa.
Aṣofin Abiọdun Aro lati ẹkun idibo Ikorodu keji sọ pe, bi ẹkun awọn ṣe sa ipa ribiribi to fun aṣeyori ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) ninu eto idibo to kọja, ipo kan ṣoṣo ni wọn fun ẹkun Ikorodu ninu orukọ naa.
Igbakeji Ọmọ ẹgbe oṣelu to pọju ninu Ile Aṣofin naa, Aṣofin Ademọla Kasumu bọkan jẹ pe, ko si orukọ ẹni kankan lati ẹkun Ikeja ninu awọn orukọ naa.
Aṣofin Nureni Akinsanya lati ẹkun Mushin ṣalaye pe, ko si orukọ kankan nibẹ lati awọn ijọba ibilẹ ati pe, ẹgbẹ oṣelu APC ni awọn akọṣẹmọṣẹ to to lati yan si iru wọn ipo yii, gẹgẹ bi Aṣofin Femi Saheed lati agbegbe Koṣofẹ ṣe gbe si ọrọ naa lẹyin.
Bakan naa ni Igbakeji Ọlọpaa Ile Aṣofin naa, Aṣofin David Setonji ṣaroye pe, awọn ti wọn mu lati ẹkun Badagry ko to nnkan rara. Aṣofin Lai Ajọmale ni tirẹ woye pe, awọn orukọ naa ti fì soju kan ju, paapaa ni ti ẹsin
Aṣofin Ọbasa wa rọ awọn ọmọ ẹgbẹ yooku lati fọwọ wọnu lori awọn awuyewuye wọn lori awọn orukọ ti Gomina fi ranṣẹ naa. O ṣalaye pe, ki wọn ṣakiyesi pe ijọba ibilẹ ko le pese alakoso-agba fun ijọba ipinlẹ.
Oludari Ile Aṣofin naa ran awọn yooku leti pe Gomina Sanwo-Olu ni ẹtọ lati yan ẹni to ba fẹ fun alakoso-agba, nigba ti ojuṣe tawọn jẹ lati ṣayẹwo awọn eniyan naa boya wọn kun oju osunwọn fun ipo naa, ki wọn si fọwọ si wọn.
Lẹyin eyi ni Oludari Ile naa pa a laṣẹ fun Akọwe-agba Ile Aṣofin naa, Amofin Ọlalekan Ọnafẹkọ lati kọwe si Gomina Sanwo-Olu lati fi orukọ awọn aṣoju lati ijọba ibilẹ si awọn ipo naa.
Leave a Reply