Take a fresh look at your lifestyle.

IWD 2023: DC, UN, UNDP Ṣé Ìsàmì Ayẹyẹ Àwọn Obìrin Nàìjíríà Pẹ̀lú Àmì-Ẹrí

2 266

Ìránṣẹ́ Orílẹ̀-èdè America sí Nàìjíríà, ní alẹ́ ọjọ́ Àbámẹ́ta, gbá àlejò ìsàmì sí ayajọ ọjọ́ àwọn obìnrin ẹlẹẹkeji irú rẹ̀ pẹ̀lú àwọ́ọ̀dù látí ṣé koriya fún àwọn obìnrin Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lórí ìdàgbàsókè ìlú àtí àwọn ọmọ Obìnrin.

Èyí ló wáyé ni Ìlú Èkó, pẹ̀lú àwọn àjọṣepọ̀ àwọn aṣojú Orílẹ̀-èdè bí Australia, Congo, European Union, France, Germany, UK, àwọn Obìnrin UN àti United Nations Development Program (UNDP) ní Nàìjíríà.

Àwọn ami-ẹri náà ní a fún awọn ẹ̀kà Aládàání, iṣẹ́ àbẹlé àtí Àwùjọ Ìlú, Olórí àtí Ìjọba, ètò ìròyìn àtí Àṣà.

Àwọn tó àwọ̀ọ́dù ní àwọn ẹ̀kà wọ̀nyí ní:
* Dame Pauline Tallen, Mínísítà fún ètò àwọn Obìnrin lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ló gbà Ààmì Ẹyẹ Àṣeyọrí ní Ìgbésí ayé
* Priscilla Iyari, Olùdarí àtí alákóso, Quickteller;
* Aisha Zannah, Olúgbèjà àwọn ọmọ Obìnrin
* Grace Alache Jerry, Olùdarí àtí Aláṣẹ, Ẹgbẹ́ Àwọn Ọrẹ ati
* Òṣèré, Kemi Adetiba, lẹ̀sẹ́sẹ́.

Mary Beth Leonard, Aṣojú AMẸRIKA sí Nigeria sọ pé “Àwọn obìnrin ló wà ní àárín gbùngbùn ounkóun pàápà jùlọ́, ìdàgbàsókè. Láti ṣé ìgbéga àtí ìdàgbàsókè fún àwọn ọmọbìnrin lórí ẹ̀kọ́ àtí ìṣòwò wọ́n.

Bákannáà Mohamed Yahya, Aṣojú tí UNDP ní Nàìjíríà ṣàpèjúwe àwọn Obìnrin Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bí “iyọ̀ láàárín àgbáyé,” ó fí kún pé gbogbo ipò gíga lágbayé ní wọ́n tí fẹ́ gbá tàn.

Àwọn mìíràn tó tún gbá àmì ẹ̀yẹ náà ní:
* Aisha Tofa fún feature Award-Digital, Innovation and Technology for Gender Equality;
* Prince Clem Agba, Mínísítà tí Ìpínlẹ̀ fún Ìṣúná àtí Ètò Orílẹ̀-èdè gẹ́gẹ́ bí HeforShe Champion: àtí
* Dókítà Abiola Akiyode-Afolabi, ajáfẹ́tọ̀ aráàlú fún ẹ̀ka Aṣáájú tó ga jù.

2 responses to “IWD 2023: DC, UN, UNDP Ṣé Ìsàmì Ayẹyẹ Àwọn Obìrin Nàìjíríà Pẹ̀lú Àmì-Ẹrí”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button