Take a fresh look at your lifestyle.

Gómìnà Seyi Makinde Búra Fún Adájọ́ Iyabo Yerima Gẹ́gẹ́ Bíi Adelé Onídàájọ́ Àgbà

0 510

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde ti búra fún Onídàájọ Yerima ni ọjọ ajé, ojo kerindinlogun osu kínní odun yìí gẹgẹ bíi Adele Onídàájọ Àgbà lẹyin ti Onídàájọ Agba Muntar Abímbólá f’eyin ti.

Ayẹyẹ ibura náà lo waye ninu ìyèwù nla to wa ni ọfisi gómìnà to wa ni agbègbè Agodi ni ìlú ìbàdàn tíì ṣe olú ìlú ìpínlè Ọ̀yọ́ ni ẹkùn gúsù iwọ oòrùn orilẹ èdè Nàìjíríà, nibi tí Gómìnà Makinde ti sàlàyé wípé ìṣèjọba òun yóo fún Onídàájọ Yerima ni atilẹyin tó yẹ láti lè ṣe ojúṣe rè bí o ti tọ àti bí o ti yẹ.

Bákan náà ni gómìnà tun sàlàyé wípé oun ni ìgboyà nínú adele Onídàájọ Àgbà náà nítorí o kún ojú oṣuwọn tí yóò sì lè tú ọkọ idajọ ni ipinlẹ Ọ̀yọ́, nígbà tí o ṣèlérí wípé ni kété ti oun ba ti wọlé ẹlẹẹkeji gẹgẹ bíi gómìnà ìpínlè Ọ̀yọ́, òun yóò mu ayípadà ọtun dé bá ẹka ìjọba náà nípa ìpèsè ohun amayederun.

Nigba tí o n sọ ìdí rè tí òun fi yan adele onídàájọ, gómìnà sàlàyé wípé, ìjọba ìpínlè Ọ̀yọ́ yan onídàájọ Yerima gẹgẹ bíi adele onídàájọ àgbà títí àsìkò tí Àjọ tó n ṣe kokaari ètò ìdájọ (NJC) yóò fi fi orúkọ onídàájọ tí wọn bá yan láti di onídàájọ àgbà tuntun síta ni ibamu pẹlu òfin orilẹ èdè Nàìjíríà.

Nigba tí o n feesi, Adele Onídàájọ Àgbà, Onídàájọ Yerima sọ wípé gbogbo ohun èlò ti ijoba ba ti pèsè fún ẹka idajọ ni òun yóò ri dájú pé o jẹ lílò fún ohun tí o ba yẹ fún ìdàgbàsókè ẹka náà àti ìwúlò èèyàn ìpínlè Ọ̀yọ́.

Onídàájọ Yerima tun fi kún ọrọ rẹ pé òun yóò sinmi le atilẹyin ti ìjọba ṣèlérí rẹ fún isedajo tó múná dóko, tí o sì tún tẹnu mọ pé afojusun òun ni lati mú kí ẹka idajọ ni ipinlẹ Ọ̀yọ́ láti tayọ nípasẹ ohun amayederun to dára. O wa fi àsìkò náà dupẹ lọwọ gómìnà fún anfààní yìí láti sìn ipinle Ọ̀yọ́, tí o sì ṣèlérí pé òun yóò sa ipá oun fún ire gbogbo ọmọ ìpínlè Ọ̀yọ́.

Abiola Olowe
Ìbàdàn

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button