Olórí Ẹgbẹ́ Ọmọ-ogun Darí Àwọn Ọmọ-ogun Láti Mú Àwọn Iṣẹ́ Ìkọlù-Ìjà-Ogun Si Àwọn Alájàngbilà Lágbára Si
Olórí Ẹgbẹ́ Ọmọ-ogun, Lieutenant General Waidi Shaibu, ti pàṣẹ fún àwọn ọmọ-ogun ti ikọ̀ 4 Special Forces Command láti mú kí àwọn iṣẹ́ ìkọlù tó lágbára pọ̀ sí i kí wọ́n sì máa tẹ̀síwájú láti ṣẹ́gun àwọn apànìyàn àti àwọn ajìjàgbara jákèjádò Nàìjíríà, kí wọ́n sì kéde òpin sí àwọn ìgbòkègbodò ìfèsìpadà nínú ìpolongo ààbò orílẹ̀-èdè Nàìjíríà

Ìròyìn kan tí Olùdarí Àgbà fún “Army Public Relations” ti awọn Ọmọ-ogun, Colonel Appolonia Anele, fi hàn pé àṣẹ náà wáyé nígbà ìbẹ̀wò àkọ́kọ́ ti ọgá agba àwọn ọmọ ológun, COAS si Ile ìwé wọn – “4 Special Forces Command and the Nigerian Army Special Forces” àti Ilé-ẹ̀kọ́ Ẹgbẹ́ Ọmọ-ogun pataki Nàìjíríà ní ilu Doma ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun.

Olórí Ẹgbẹ́ Ọmọ-ogun fi dá àwọn òṣìṣẹ́ lójú pé àlàáfíà àwọn ọmọ-ogun àti ìdílé wọn lo jẹ́ wọn lógun, ó tẹnumọ́ pé agbára tí ó ní ìpìlẹ̀ àti ìrànlọ́wọ́ tó péye ṣe pàtàkì láti mú kí iṣẹ́ máa lọ síwájú. Ó ṣèlérí láti máa jé ki tẹẹ síwájú, ètò ìṣiṣẹ́, àti àwọn ohun èlò ìjà òde òní láti rí i dájú pé àwọn akoni Ọmọ-ogun ń borí àwọn ọ̀tá.

Ìbẹ̀wò náà parí pẹ̀lú ìdánrawò gbígbìn igi ní agbègbè náà, èyí tí ó fi hàn pé wọ́n ní ìfaramọ́ sí ojúṣe àyíká àti ìdàgbàsókè tó pẹ́ títí láàrín àwọn ẹgbẹ́ ọmọ-ogun Nàìjíríà.

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san