Take a fresh look at your lifestyle.

Àjọ Badminton Federation of Nigeria Tún Francis Orbih Yan

85

 

Francis Orbih ni wọ́n ti tún yàn gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ àjọ Badminton Federation of Nigeria (BFN) fún ìgbà kẹta ní ìtẹ̀léra, lẹ́yìn tí ó jáde ní ipò láìsí alátakò ní ìpàdé ìdìbò ẹgbẹ́ náà.

Ní ìdìbò tí wọ́n ṣe ní ọjọ́ kejì oṣù kẹta ní Pápá Ìṣeré Moshood Abiola National Stadium ní Abuja, wọ́n tún yan Adamu Alhaji Lawan gẹ́gẹ́ bí Igbákejì Ààrẹ láìsí alátakò.

Nínú ọ̀rọ̀ ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀, Orbih kí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ìgbìmọ̀ tuntun tí wọ́n yàn án, ó sì fi ìgbẹ́kẹ̀lé hàn nínú agbára àpapọ̀ wọn láti mú eré náà tẹ̀síwájú.

Ó wà pe fún ìṣọ̀kan àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ láàárín àwọn alenulọ́rọ̀, ó sì tẹnu mọ́ pé a ìdàgbàsókè ere badminton ní Nàìjíríà ṣe pàtàkì.

Ogbeni Dikko rọ Ààrẹ tí wọ́n tún yàn láti tún so àwọn àǹfààní tí wọ́n ti rí gbà nígbà tí ó wà ní ipò tẹ́lẹ̀ pọ̀ kò le dandain, kí ó sì mú kí àwọn ìsapá túbọ̀ pọ̀ sí i láti mú eré náà dàgbàsókè sii ní ọdún mẹ́rin tó ń bọ̀.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button