Ìyàwó Ààrẹ orílẹ-èdè Nàìjíríà, Oluremi Tinubu ti ṣi iṣẹ́ Ilé Ìjọsìn Gbọngán Ààrẹ ti Kristẹni- National Assembly Chapel,, tí Ẹgbẹ́ Àwọn Aṣòfin Kristẹni ti Orílẹ̀-èdè yìí kọ́.
Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ níbi iṣile náà, tí àwọn olórí orílẹ̀-èdè pàtàkì wà ayá Ààrẹ sọ pé, inú òun dùn pe, pipari iṣẹ́ ilé ìjọsìn náà ṣe oju òun.
Ó sọ pé “ilé ìjọsìn náà dúró gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí pé bí àwọn aṣòfin bá ń ṣe òfin fún àwọn ènìyàn, wọ́n ń jíhìn fún Ọlọ́run ni”

Ní gbígbé àdúrà rẹ̀ ka orí iwe Kíróníkà ori kefa, ese kọkàndínlógoji sí ogójì, 6:39–40, ó gbàdúrà pé kí Ọlọ́run dáhùn gbogbo àdúrà tí wọ́n bá gbà nílé ìjọsìn náà.
Ààrẹ Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Àti Alága Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Àpapọ̀, Sẹ́nétọ̀ Godswill Akpabio, sọ pé inú òun dùn sí ìmúṣẹ ilé ìjọsìn náà.
Ó sọ pé, kí àwọn òfin tó wà kárí ayé, Ọlọ́run ti fi ìdájọ́ òdodo lélẹ̀ ní ìpìlẹ̀ ayé.
Ó rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà láti máa gbàdúrà fún orílẹ̀-èdè yii, ó sì gbóríyìn fún gbogbo àwọn aṣòfin àti àwọn ará ìlú tí wọ́n ṣe alabapin sí ìmúṣẹ iṣẹ́ náà.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san