Take a fresh look at your lifestyle.

Ikọ̀ Super Falcons Subú Yakata Sí Ọwọ́ Cameroon Ní Yaoundé Níbi Ìfagagbága Ọlọ́reẹ́sọ̀rẹ́

99

 

Àwọn ikọ̀ Super Falcons ti orílẹ-èdè Nàìjíríà ba ìjákulẹ̀ pade sí owọ́ ikọ̀ Indomitable Lionesses ti orílẹ-èdè Cameroon ní ìdíje Oloresore ní pápá Ìṣeré Ologun ní Yaoundé ní ọjọ́ Àbámẹ́ta pẹlu ayo kan dondo(1-0).

Ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Super Falcons tó ń joba ní ilè Adúláwọ̀, ló ṣàkóso púpọ̀ ju ninu ifagagbaga náà nípa dídá àwọn adeyinmu ikọ̀ Cameroon rìgborìgbo síbẹ̀síbẹ̀, wọn kò leè ṣe àṣeyọrí ní ojọ́ náà.

Ikọ̀ ti Nàìjíríà ṣe ọ̀pọ̀ àyípadà lẹ́yìn ìsinmi ránpẹ́ bí wọ́n ṣe ń wá ọ̀nà láti wó ikọ̀ Cameroon lulẹ̀ sugbọn ẹpa kò boro mọ́.

Bí ìdíje náà ṣe ń lọ sí siwaju , ògbóntàrigi agbábọ́ọ̀lù fún ikọ̀ orilẹ-ède Cameroon, Mbomezomo Yvana lo àǹfààní ìfàsẹ́yìn díẹ̀ nínú ti ikọ̀ Nàìjíríà ni láti gba olùborí fún ikọ̀ Cameroon.

Super Falcons kò ní àkókò púpọ̀ láti dúró de àǹfààní láti ra igba padà. Àwọn ikọ̀ mejeeji yóò tun wàkò ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun, Oṣù Kẹta Ọjọ́ keta, Ọdún 2026, fún ìpele kejì ti ìforígbárí oníbejì.

Àwọn ìdíje náà yóò ṣiṣẹ́ fún ìpalẹ̀mọ́ fún idije àwọn Obìnrin ti Áfíríkà ti Ọdún 2026 (WAFCON), fún àwọn orílẹ̀-èdè méjèèjì.

 

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button