El-Kanemi Warriors bori ikọ̀ Abia Warriors ní àmì ayò meji sì odo 2-0 ní ọjọ́ ìdíje ọjó kejidinlogbon ti Nigerian Premier Football League (NPFL), ní pápá isere El-Kanemi Warriors Sport Complex ní ilu Maiduguri, ipinle Borno.
Agbábọ́ọ̀lù ní ipò aarin, Daddy Abdulrahman, ló gba bọọlu wọlé fún ìkọ El-kanemi Warriors nibi ayo golí wòó ki gba siọ ní iṣẹju mejilelogun.

Lẹ́yìn náà, àwọn olùgbàlejò náà tun tẹẹ síwájú latẹsẹ̀ Bashir Musa ní ìṣẹ́jú merindinlaadorun, 86 mins láti gba àmì mẹ́ta (3) fún ìkọ El-Kanemi Warriors.
El-Kanemi Warriors ti gbéra pa sí ipò kẹfà lórí tábìlì pẹ̀lú àmì mokanlelogoji, (41 points) láti inú àwọn ìdíje mejidinlogbọ̀n, 28, nígbà tí Abia Warriors wà ní ipò karùn-ún pẹ̀lú àmì metalelogoji, (43points).
Àwọn àbájáde idije NPFL ti ọjọ́ Àbámẹ́ta ní wọnyii:
El-Kanemi Warriors 2-0 Abia Warriors
Kwara United, ọkan sì odo 1-0 Wikki Tourist.
El-Kanemi Warriors, meji sì odo 2-0 Abia Warriors
Kwara United, ọkan sì odo1-0 Wikki Tourist.

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san