Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Ghana Yóò Sí Ilé Ẹjọ́ Áfíríkà Ní Orílẹ̀-èdè Tanzania

58

 

Ààrẹ John Dramani Mahama ti ilẹ Ghana yóò kúrò ní ilu Accra ní ọjọ́ Àìkú, Oṣù Kẹta ọjó kinni odun 2026, lọ sí Arusha, orilẹ-ede Tanzania, níbi tí yóò ti jẹ́ Àlejò pàtàkì níbi ayẹyẹ pàtàkì kan láti ṣí Ilé Ẹjọ́ Afirika lórí Ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn àti Ènìyàn ní ọjọ́ Ajé ní ọdún ayajọ idajọ ọdún 2026.

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn àjọ APO Group sọ ní ipò Ààrẹ, Orílẹ̀-èdè Ghana, ayẹyẹ náà yóò tún jẹ́ láti ṣe ìfilọ́lẹ̀ ògún ọdún ti ilé ẹjọ́ náà.

“Nígbà tí ó bá wà ní Arusha, Ààrẹ Mahama yóò bá Ààrẹ Tanzania, Ọ̀gágun Samia Suluhu Hassan, sọ̀rọ̀.

“Ọ̀gbẹ́ni Mahama yóò kúrò ní Arusha lẹ́yìn ètò ìbẹ̀rẹ̀ ayẹyẹ ní ọjọ́ Ajé, nígbà tí ó bá sì lọ, Igbákejì Ààrẹ yóò ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ ní ìbámu pẹ̀lú Àpilẹ̀kọ ọgọta ìpele kẹjọ, 60(8) ti Ìwé Òfin,” ìròyìn náà fi kún un.

 

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

 

 

Comments are closed.

button