Take a fresh look at your lifestyle.

Ọlópàá Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Tú Ẹgbẹ́ Oníṣòwò Ọta Ìbọn Ká, Wọ́n Gba Ọta Ìbọn 2,625 Padà.

18

Ni ìbámu pẹ̀lú ìpinnu ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ láti dẹkùn ìwà ìdigunjalè ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ati àwọn agbègbè to yìí ká, ẹ̀ka ilé iṣẹ́ yìí tó kalẹ̀ sí Ṣakí tí mú afurasí méjì kan ni agbègbè Budo Mọsalasi ní ilú Ṣakí.

Àwọn afurasí méjì náà ni Isiaka Dare, ẹni ọdún Márùndínlógójì (35) àti Taiwo Ayodabo, ẹni ọdún Mẹ́tàlélọ́ngbọ̀n (33), ti àwọn méjèèjì jẹ́ ọmọ ìlú Tede ni iṣẹ́ ìwádìí àwọn Ọlọ́pàá fi hàn pé wọn lọ́wọ́ nínú ìṣòwò ọta ìbọn láti Orílẹ̀ èdè Olómìnira Benin (Benin Republic) wá sí Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, eléyìí tó ṣeéṣe kí wọ́n tà fún àwọn adigunjalè, ajínigbé àti àwọn ọdaràn míràn.

Àwọn ohun tí ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá ri gbà lọ́wọ́ wọn ni àpò ọta ìbọn Márùnlélọ́gọ́rùn ún (105), eléyìí tí wọ́n pamọ́ sínú gálọ̀nù omi mẹ́rin (4). Àlàyé Alukoro ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, DSP Olayinka Ayanlade tún fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àpò kọ̀ọ̀kan ní kátíríìjì márùnlélógún (25) nínú rẹ̀, ti àpapọ̀ gbogbo rẹ̀ sì jẹ́ (2,625).

Bákan náà ni wọn tún gba Alùpùpù méjì tí kò ní nọmba ìdánimọ̀, eléyìí tí wọ́n gbà pé òun ni wọ́n n lò fún gbígbé àti pínpín ọta ìbọn náà ní ọ̀nà tí kò bá ófin mu. Ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá jẹ́ kó di mímọ̀ pé àwọn afurasí náà jẹ́wọ́ ẹ̀sùn náà, tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn agbofinro lójúnà àti mọ àwọn míràn tí wọn tún lọ́wọ́ sí ìṣòwò ọta ìbọn láti Orílẹ̀ èdè kan sì ìkejì.

Lẹ́yìn èyí ni Kọmíṣọ́nà Ọlọ́pàá, Fẹmi Haruna ti pàṣẹ pé kí wọ́n gbé àwọn afurasí náà lọ sí ilé ẹjọ́ lẹ́yìn ti ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá bá parí isẹ́ ìwádìí wọn. Kọmíṣọ́nnà Ọlọpàá Haruna wá gbé òṣùbà káre fún àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ fún ọgbọ́n inú àti ìlànà à tẹ̀lé, pẹ̀lú ìgbésẹ kánkán eléyìí tó jẹ́ kí wọ́n rí àwọn afurasí náà mú.

Bákan náà ni Kọmíṣọ́nnà Ọlọpàá dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ará ìlú tí wọn fi ìṣẹ̀lẹ̀ yìí tó ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ létí, tó sì tẹnu mọ́ pé ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ara ìlú se pàtàkì láti dojú ìjà kọ ìwà ọ̀daràn.

O tún fi dá ará ìlú lójú pé ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ kò ní gba ki Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ jẹ ibùba fún ìwà òdaran àti àwọn ọdaràn. Kọmíṣọ́nnà wá rọ àwọn ènìyàn láti túbọ̀ tẹ síwájú lójúnà àti máa pèsè ìròyìn tó yẹ fún ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá.

Abiola Olowe
Ìbàdàn

Comments are closed.

button