Take a fresh look at your lifestyle.

Igbákejì Ààrẹ Shettima Fọwọ́ Ṣí Àkójọpọ̀ Ìgbìmọ̀ Àwọn Oníròyìn Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà

25

Igbákejì Ààrẹ  Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Kashim Shettima ti tún fi hàn pé ìjọba Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti fi àkójọpọ̀  ti Ìgbìmọ̀ Àwọn Oníròyìn Nàìjíríà hàn, ó sì tẹnu mọ́ àǹfààní ọrọ̀ ajé àti ìrìn àjò afẹ́ ti gbogbo ìpínlẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà 

Ó ṣàpèjúwe Ààrẹ Bola Tinubu gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ àwọn oníròyìn àti onígbàgbọ́ tó lágbára nínú òmìnira àwọn oníròyìn, ó ṣàlàyé wí pé ìjọba Tinubu, láàárín ọdún mẹ́ta sẹ́yìn, ti gbé àyíká kan kalẹ̀ tí ó fún àwọn oníròyìn láyè láti ṣiṣẹ́ láìsí ìhalẹ̀mọ́ni.

Igbákejì Shettima sọ ọ̀rọ̀ yìí nígbà tí ó ń gba àwọn aṣojú láti Ìgbìmọ̀ Àwọn Oníròyìn Nàìjíríà (NPC), ati  Akọ̀wé Àgbà àti Olórí Àgbà wọn, Dókítà Dili Ezughah, alejò ni ilu Abuja.

Ó sọ wí pé àwọn ènìyàn sábà máa ń sọ ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn tàbí ọ̀rọ̀ ìbínú sí ìjọba, síbẹ̀ wọn kò ní gbẹ̀san nítorí ìfaradà Ààrẹ Tinubu

Bákanáà, Igbákejì Gómìnà Ìpínlẹ̀ Bauchi, Mohammed Jatau, ní ipò Gómìnà Bala Mohammed, fi ọpẹ́ hàn sí àwọn olórí àpapọ̀, ó sọ wí pé àkójọpọ̀ náà yóò jẹ́ kí ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan ṣe àfihàn ìrìn àjò àti agbára ọrọ̀ ajé wọn.

Akọ̀wé Àgbà ti NPC, Dókítà Ezughah, dúpẹ́ lọ́wọ́ Igbákejì Ààrẹ fún fífún Ìgbìmọ̀ Ètò NPC ní àwùjọ, ó sì jẹ́wọ́  wí pé òun ń ṣe àtìlẹ́yìn fún ìdàgbàsókè ọrọ̀ ajé orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti ìṣọ̀kan to dúró.

Ó ṣàlàyé wí pé àkójọpọ̀ àwọn ìròyìn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí wọ́n ń ṣe àgbékalẹ̀  ṣe àfihàn àwọn ohun èlò ìṣúná owó àti ìrìn àjò orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ó sì nílò ìtọ́sọ́nà ìlànà ti Igbákejì Ààrẹ lórí ìwé náà.

Comments are closed.

button