Take a fresh look at your lifestyle.

Àdéhùn: Ilé ìgbìmọ̀ Aṣòfin Pè Fún Sí San Owó Bi Ti  Àtẹhìnwá.

47

Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin  Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, nípasẹ̀ Ìgbìmọ̀ Ìnáwó rẹ̀, ti rọ Ìjọba Àpapọ̀ láti padà sí Ètò Ìsanwó Àtijọ́, ó sọ wí pé ọ̀nà tí a ṣètò lọ́wọ́lọ́wọ́ ti jẹ́ kí ó jẹ́ gbèsè fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn oníṣẹ́, títí kan àwọn tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ní ọdún 2024, kí a má tilẹ̀ sọ èyí tí a yàn fún ọdún 2025.

Ìgbìmọ̀ náà tún wá ọ̀nà láti rọ́pò ètò ìṣúná owó Àpò ìwé pẹ̀lú àfojúsùn tàbí àpẹẹrẹ ìṣe, gẹ́gẹ́ bí ó ti béèrè  wí pé kí a yọ Akọ̀wé Àgbà ti Ilé Iṣẹ́ Àjọ (CAC), Hussaini Ishaq Magaji, kúrò, fún àìgbọ́dọ̀ máṣe láti farahàn níwájú ìgbìmọ̀ náà.

Nínú ọ̀rọ̀ wọn lọ́tọ̀ọ̀tọ̀, gbogbo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ìgbìmọ̀ náà tẹnu mọ́ ìlà Alága nípa ṣíṣí àwọn ẹgbẹ́ ọrọ̀ ajé láti jókòó fún ètò ìṣúná owó àti ìmúṣẹ tí ó dára jù, àti láti san owó ni kíákíá fún àwọn oníṣẹ́.

Nínú ìdáhùn wọn, ẹgbẹ́ ọrọ̀ ajé fi dá ìgbìmọ̀ náà lójú, àti nípa àfikún, àwọn ọmọ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà,  wí pé ìrètí fún ọdún 2026 dára gan-an fún ìṣúná owó tí a gbé kalẹ̀ fún N58.472trillion ní ti ìmúṣẹ.

Ogbeni Edu salaye fun igbimo náà wí pe eto isuna owo ti Orílè-èdè Nàìjíría naa ni lọwọlọwọ ko ni lati gba owo ti a ya nikan

Ile igbimo asofin so  wí pe won ni aniyan nipa awon oro ti ko yanju nipa atunse owo-ori CAC ati wí pe wọn ti hale lati da ifọwọsi isuna owo ti odun 2026 duro fun igbimo náà.

Aare Tinubu yan Magaji si ipo yii ni ojo ketala osu kewa odun 2023.

Gẹgẹbi Akọwe-Agba ti CAC, a nireti pe Magaji yoo ṣiṣẹ fun idagbasoke ati ilana awọn ọran ile-iṣẹ ni Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Comments are closed.

button