Take a fresh look at your lifestyle.

Mínísítà Fún Iṣẹ́ Nàìjíríà Bú-Ẹnu-Àtẹ-Lú Ìwà Ìbàjẹ́ Ni Òpópónà Èkó Sí Calabar

132

Mínísítà fún Iṣẹ́ ní Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Dave Umahi, tí bú-ẹnu-àtẹ-lú àwọn ìwà ìbàjẹ́ àwọn ènìyàn ní òpópónà Èkó sí Calabar, Ó sí kìlọ̀ pé ọwọ́ òfin yóò mú àwọn tó ń hu ìwà ìbàjẹ́ náà.

‎ Mínísítà ṣe ìkìlọ náà nígbà àyẹwò iṣẹ rẹ̀ ní Èkó, níbití o tí sọ̀rọ̀ nípa bí wọ́n ṣe n gé àwọn ìrìn iṣẹ́ àkànṣe náà àti dídá àwọn ìdọ̀tí sí ojú òpópónà.

‎O dupẹ lọwọ Kọmíṣọ́nà Ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Èkó àti Ọgá Ọlọ́pàá pátápátá fún ìgbésẹ̀ ààbò láti dáàbòbo òpópónà iṣẹ náà.

‎Umahi fí kún un pé Ilé-Iṣẹ́ Ìjọba Àpapọ̀ náà yóò pèsè epo àti owó láti ṣètìlẹ́yìn àti láti mú kí iṣẹ́ olùṣọ́ ní ojú ọ̀nà náà lágbára sí i.

‎Umahi ṣàpèjúwe gígé àwọn ìrìn ọgbà òpópónà náà àti dídá ìdọ̀tí sínú ihò ọ̀gbàrá àti ojú pópó gẹ́gẹ́ bí òun tí kò dára, ó sì tẹnu mọ́ ọn pé irú àwọn ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ yóò ba ìsapá ìdàgbàsókè orílẹ̀-èdè jẹ́.

‎Ó sọ pé a óò gbé àwọn ìgbésẹ̀ ìgbà díẹ̀ kalẹ̀ láti dí àwọn ihò náà àti láti dènà wíwọlé sí ọnà náà láìgbàṣẹ. Mínísítà náà tún sọ pé ìkún omi tí a ń dojúkọ ní apá kan ojú ọ̀nà náà jẹ́ nítorí ìdọ̀tí tí a dà sínú ihò ìdamínù.


‎Ó rọ̀ àwọn olùgbé àdúgbò náà láti dáàbò bo àwọn ètò ìṣiṣẹ́ gbogbogbòò náà kúrò lọ́wọ́ ìbàjẹ́ àti ìlòkulò.

Comments are closed.

button