Take a fresh look at your lifestyle.

DG VON Ṣèbẹ̀wò Sí Gómìnà Ìpínlẹ̀ Nasarawa Fún Ìbáṣepọ̀ Ìròyìn Tó Lágbára

113

Olùdarí Àgbà fún Ilé Akéde Nàìjíríà (Voice of Nigeria VON), Mallam Jibrin Baba Ndace, ti ṣe ìbẹ̀wò sí Gómìnà Ìpínlẹ̀ Nasarawa, Abdullahi Sule, ní Ilé Ìjọba ní Lafia, èyí tó ń mú kí àjọṣepọ̀ láàrín àwọn oníròyìn àgbáyé àti ìjọba ìpínlẹ̀ náà lágbára síi.

‎ Mallam Ndace fi ìmọrírì rẹ̀ hàn fún ìtìlẹ́yìn Gómìnà náà nígbà gbogbo, ó sì tún fi ìdánilójú láti ṣe ìpolongo àwọn ètò ìlànà, àǹfààní ìdókòwò ti Ìpínlẹ̀ Nasarawa fún àwọn olùgbọ́ rédíò náà kárí ayé.

‎Ó ṣe àkíyèsí pé VON ń gbé ìròyìn jáde pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdè gẹ́gẹ́ bí Gẹ̀ẹ́sì, Hausa, Yorùbá, Fulfulde, Swahili, àti èdè Lárúbáwá, èyí tó mú kí àwọn ìtàn Nàìjíríà dé ọ̀dọ̀ onírúurú olùgbọ́ kárí ayé.

‎DG náà tẹnu mọ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì tí a kọ sílẹ̀ lábẹ́ ìdarí rẹ̀, ó sì ṣàlàyé ìran ètò VON láti mú kí ìtẹ̀síwájú bá àwọn ìròyìn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà gbòòrò síi kárí ayé, pẹ̀lú ìpinnu láti mú èdè Mandarin kun àwọn èdè tí a ún gbé safẹfẹ tẹlẹ láti ṣàfihàn ìtẹ̀síwájú VON àti ìsapá àtúnṣe tí ó ń lọ lọ́wọ́ láti ọwọ́ Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu láti mú ìgbékalẹ̀ VON padà sípò.

Comments are closed.

button