Take a fresh look at your lifestyle.

Rivers United Pàdánù Nínú Ìdíje ‘CAF Champions League ‘

193

Ikọ Rivers United pàdánù ní àmì ayò mẹ́ta sí òdo (3-0) sí ọwọ́ ikọ RS Berkane nínú ìdíje ‘CAF Champions League’ nínú ifẹsẹwọnsẹ ikẹ́yìn wọn, wọ́n sì parí sí ìsàlẹ̀ tábìlì.

‎ Olùgbàlejò RS Berkane fi agbára rẹ̀ hàn ní ìbẹ̀rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gba ayò wọlé ní ìṣẹ́jú márúndínlogójì (35 minutes) nígbà tí Youssef Mehri gba bọ́ọ̀lù wọlé.


‎Berkane tẹ̀síwájú láti pàṣẹ eré náà ó sì tún ṣe àṣeyọrí rẹ̀ ní ìṣẹ́jú méjìlèlogójì (42 minutes) láti ẹsẹ Paul Valère Bassène.

‎Ẹgbẹ́ Berkane náà fi ìdí àbájáde náà múlẹ̀ ní kété lẹ́yìn ìdá méjì tí ifẹsẹwọnsẹ naa. Ní ìṣẹ́jú mẹ́talélàádọ́ta (53 minutes) láti ẹsẹ̀ Paul Valère Bassène ní ẹlẹ́ẹ̀kejì.

Àwọn àbájáde ifẹsẹwọnsẹ ọjọ́ Àbámẹ́ta ní wọnyi:

Mamelodi Sundowns 2-0 MC Alger

Al Hilal SC 1-0 FC Saint-Eloi Lupopo

ES Tunis 2-0 Atletico Petroleos

Simba FC 1-0 Stade Malien

RS Berkane 3-0 Rivers United

Pyramids FC 3-1 Power Dynamos.

Comments are closed.

button