Take a fresh look at your lifestyle.

‎Ìjọba Kwara Dáhùn Sí Àfihàn Fídíò Àwọn Ẹni Tí Wọ́n Jígbé

101

Ìjọba Ìpínlẹ̀ Kwara, Àárín Gbùngbùn Àríwá Nàìjíríà, sọ pé ó bá àwọn nínú jẹ gidigidi lórí fídíò ìdààmú tí àwọn oníjàgídíjàgan ṣe jáde láìpẹ́ yìí tí wọ́n ṣàfihàn àwọn ènìyàn tí wọ́n jigbé nígbà ìkọlù ìbànújẹ́ kán ní ọjọ́ kẹta oṣù Kejì ọdún yìí ní agbègbè Woro.

‎“Gẹ́gẹ́ bí ìgbà gbogbo, èrò wa wà pẹ̀lú gbogbo ìdílé tí àwọn ènìyàn wọn wa ní àhámọ́ yìí, a sì tún ṣàfihàn ìdúróṣinṣin láti rí i dájú pé gbogbo wọn gbá ìtúsílẹ̀ láìléwu” ìjọba ìpínlẹ̀ náà sọ nínú ìkéde kan tí Kọmíṣọ́nà Ìpínlẹ̀ fún Ìbánisọ̀rọ̀, Bolanle Olukoju fi síta.”

‎Gẹ́gẹ́ bí ìkéde náà ti sọ, ìjọba sọ pé àwọn mọ ìbànújẹ tí fídíò náà lè fa fún àwọn àníyàn ṣùgbọ́n ó kéde pé àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba àti àwọn ilé iṣẹ́ ààbò ń ṣe àyẹ̀wò fídíò náà dáadáa láti fi ìdámọ̀ àwọn ènìyàn tí wọ́n fihàn hàn.

Comments are closed.

button