Take a fresh look at your lifestyle.

Orílè-èdè Malawi Ṣe Ìfilọ́lẹ̀ Ètò Abẹ́rẹ́ Àjẹ́sára  Rọmọlápá Rọmọlésẹ̀

27

Orílè-èdè Malawi ti bẹ̀rẹ̀ ètò  abẹ́rẹ́ àjẹ́sára rọmọlápá rọmọlésẹ̀ káàkiri ìlú ìṣòwò Blantyre lẹ́yìn tí wọ́n ko fi ri àìsàn nàá nínú àwọn àyẹ̀wò ti wọn ṣe 

Ìgbésẹ̀ náà ń fojúsùn àwọn agbègbè mẹ́jọ ti Blantyre, èyí tí ó jẹ́ ìlú kejì tí ó tóbi jùlọ ní orílẹ̀-èdè náà.

Dókítà Ìlera Gbogbogbòò ní Àjọ Ìlera Àgbáyé, Dókítà Akosua Ayisi ṣàlàyé wí pé àwọn ọmọdé tí kò tíì pé ọmọ ọdún márùn-ún ló ní ewu àrùn náà lára.

Kò sí ìwòsàn fún polio, èyí tí ó mú kí àwọn ètò àjẹsára ṣe pàtàkì sí i.

Àwọn òṣìṣẹ́ ìlera ní ìrètí láti ṣe ètò náà ní àwọn agbègbè púpọ̀ sí ki àìsàn nàá ma ba gbilẹ kaakiri.

Àwọn àmì polio ní àárẹ̀, ibà, ìgbẹ́ gbuuru àti orí fífó. Ní àwọn ọ̀ràn líle koko, ó lè yọrí sí àrùn rọmọlápá rọmọlésẹ̀.

Comments are closed.

button