Ìjọba Ìpínlẹ̀ Plateau ti ṣe àkọsílẹ̀ ohun tí ó ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí ìdàgbàsókè pàtàkì nínú ìjàkadì ìtajà ènìyàn lẹ́yìn ìkọlù alẹ́ kan tí ẹgbẹ́ Alátakò Ìtajà Ènìyàn ti ìpínlẹ̀ Plateau ṣe, èyí tí ó yọrí sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbàlà àwọn ẹni tí ó jẹ́ aláìlera ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ibi ní ìpínlẹ̀ náà.
Agbẹjọ́rò Àgbà àti Kọmíṣọ́nà fún Ìdájọ́, tí ó tún jẹ́ alága ẹgbẹ́ Ìtajà Ènìyàn ní ìpínlẹ̀ Plateau , Adájọ́ Philemon Daffi kéde pé iṣẹ́ náà ṣe àmì ìyípadà nínú ìpolongo ìpínlẹ̀ náà.
Gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ, ìkọlù àṣeyọrí náà jẹ́ àbájáde oṣù mélòó kan ti àtúnyẹ̀wò ìlànà, ìkójọ ìmọ̀ tí a fi dátà ṣe, àti àtúntò ètò iṣẹ́ ẹgbẹ́ Alátakò náà.
Ó kìlọ̀ wí pé àwọn àgbàlagbà tí wọ́n ń tọ́jú àwọn ọmọdé yóò dojúkọ ẹjọ́ pátápátá ,ó sì sọ wí pé àwọn yóò máa ṣe irú àwọn ẹniyan bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí apanijẹ àti pé wọn yóò jẹ́bi gẹ́gẹ́ bí àwọn oníṣòwò.
Ó tẹnu mọ́ wí pé àwọn ọ̀daràn kò gbọdọ̀ retí ìtanràn tàbí ìtùnú, nítorí pé ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ẹgbẹ́ náà òun fẹ́ lo gbogbo ìwúlò òfin náà.
Nínú ìkìlọ̀ líle sí àwọn oníṣòwò àti àwọn alábáṣiṣẹpọ̀ wọn, Agbẹjọ́rò Àgbà sọ wí pé ìjọba dúró ṣinṣin àti pé wọ́n ń ṣe àtúnṣe ní ti ìmọ̀ ẹ̀rọ láti tọ́pasẹ̀ àwọn ọgbọ́n ọ̀daràn tó ń yípadà.
Ó tún fi ìdánilójú wi pé ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ náà yóò máa kọ́ agbára wọn nígbà gbogbo, ìdánilẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì, àti ìdàgbàsókè àwọn ètò ìtúnṣe fún àwọn tí wọ́n gbàlà.