Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Tinubu kí àwọn  Ẹgbẹ́ Agbábọ́ọ̀lù Orílè-èdè Nàìjíríà lẹ́yìn ìṣẹ́gun Super Bowl

17

Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti kí àwọn agbábọ́ọ̀lù Nàìjíríà nínú ẹgbẹ́ Seattle Seahawks, lẹ́yìn ìṣẹ́gun ẹgbẹ́ náà lórí New England Patriots nínú Super Bowl 60, tí wọ́n ṣeré ní ọjọ́ Àìkú ní pápá ìṣeré Levi’s Stadium ní Santa Clara, California.

Ààrẹ Tinubu tún yin Michael Onwenu ti New England Patriots, ó ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn agbábọ́ọ̀lù tó lágbára jùlọ nínú eré náà, ẹni tí ìṣe rẹ̀ ní apá kejì fi hàn pé ipa àwọn ọmọ Nàìjíríà ń pọ̀ sí i nínú eré ìdárayá àgbáyé tó gbajúmọ̀.

Ààrẹ Tinubu yin àwọn Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù naa fún gbígbé Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà  ga sí orí ìtàgé àgbáyé, ó sì sọ wí pé gbígbé àsíá Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà sókè gẹ́gẹ́ bí àmì tí Emmanwori, Nwosu àti Maye gbé sókè lẹ́yìn ìṣẹ́gun náà fi hàn wi pé wọ́n jẹ ọmọ Orílè-èdè réré.

Ó sọ wí pé ó jẹ́ ìṣírí fún àwọn ọ̀dọ́mọdé Nàìjíríà nílé àti ní àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn.

Ó fi kún un wí pé àwọn àṣeyọrí àwọn agbábọ́ọ̀lù náà fi orúkọ rere  Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà múlẹ̀ fún ìtayọ, ìfaradà àti ẹ̀bùn eré ìdárayá, nígbà tí ó ń tẹnu mọ́ wí pè o fi há wí pé orílẹ̀-èdè Nàìjíríà náà ní ènìyàn tó pọ̀.

Ààrẹ Tinubu fẹ́ kí àwọn òṣèré náà ní àṣeyọrí àti tó pọ̀ sí i nínú iṣẹ́ wọn, ó sì rọ̀ wọ́n láti máa ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí aṣojú tó yẹ ní Nàìjíríà níbikíbi tí wọ́n bá ti ń díje.

Comments are closed.

button